Sunday, June 14, 2009

JUNE 12 KO SE E GBAGBE O.

Awon Ajaja n Gbara ati awon Egbe Ajafeto ti se opolopo eto lati fi han pe ayajo ojo June 12, ko parun, ati pe ki ijoba ye e ka Ojo 29 Osu Ebibi (May 29), ni ojo isami iselu fun wa mo, June 12, gan ni ojo ti o ye ki won ya soto ni ile Naijiria fun ayajo isami iselu.
Ni tooto, ojo mejeeji yii ni ami ni orile ede wa, sugbon awon ajajangbara n taku se, pe ko si ojo miran ti a se eto idibo ti o kese jari julo ni ile wa Naijiria bi ko ba se June 12, 1993.
Won fe ki ijoba mo ojo yii gege bi ojo ti a se eto idibo ti o dangajia julo ni ile Naijiria, ki won si ye eni ti won ni o yege ibo naa ti ko si ri opa ase gba Oloye Moshood Olawale Kasimawo Abiola si la ti fi mo riri ise gidi ti o se.
Awon egbe ajaja n gbara ati ajafe to bi CLO, CDRP, CDDR, ati awon toku, se ayeye isami naa ni Eko, Abuja ati Osogbo lati sami june 12.
Egbe oselu Onigbale (AC), mu ileri won se lati ba won kopa ninu gbogbo eto ti won ba se lati sami ojo naa.
Humphrey Nwosu, ti o je alaga eto idibo nigba naa bee re pe ojo wo ni a tun le pe ni ayajo ojo ti a se eto idibo ti o kese jari julo ni ile wa Naijiria, o ni ojo june 12 ni gbogbo omo Naijiria ni tile toko so eleyameya nu, won ko ti e wo esin, won ko si wo ti asa, won ko si wo ti ede tabi ipinle ti won si huwa bi awon eeyan ilu olaju bi America tabi Britain.
Lai Mohammed ti o je alukoro egbe Onigbale (AC) lapapo naa so wi pe June 12 ti di apeere fun ile Naijiria gege bi ojo ti a se eto idibo ti o kese jari julo. Ni ojo naa, eeyan kan ibo kan ni ti ko si ni se pelu esin tabi eya, ojo yii gan an ni awon eeyan yan Aare won funra won ninu ibo ti o rorun julo bi o ti wi.
Mohammed ni egbe onigbale n fe ki won ya ojo naa soto fun ayajo ojo iselu eyi ni o le je ki ijoba ti wa n ti wa o tu bo tewon si. O wa ni, ni gbogbo igba ti ijoba ko ba ti fi aaye gba ojo yii gege bi ayajo ojo iselu, awon eeyan ti won lodi si ijoba ti wa n ti wa naa ni yoo si ma yan awon eeyan je ti won ko fi ni le yan adari ti o je ti won.
"Awon ijoba ti o wa lode ni asiko yii n se nnkan ti won fe ni, nitori kii se awon eeyan funra won ni won yan won, won ko si le jabo fun won. Ni awon Ipinle Eko ati Edo ti o je pe awon eeyan ni o yan ijoba won fun ra won, awon gomina won n jabo fun won , won si ti di arikose fun awon to ku fun isejoba rere."
Gomina meji Ipinle Eko ati Ogun ilu Bashorun Abiola fun awon osise won ni isinmi lati sami ayajo ojo naa, Fashola ni ayajo ojo naa gan an ni ojo iselu to si julo ni ile wa Naijiria.

No comments:

Post a Comment