Wednesday, April 22, 2009

IJOBA N GBE IGBESE LORI INA MONAMONA

Ijoba ti bu owo lu ise ero amuna wa lanaa, pelu owo bilionu meedogun(n15bn), eyi ja si pe laipe, ina monamona yoo yato si ti ateyinwa.
Ajo ti o n ri si ipese ina monamona aladani, iyen (National Independent Power Project), ti igbakeji Aare Goodluck Jonathan je alaga re ni won ti gba ise naa wole.
Gbigba wole yii waye ni deede osu kan ti ajo naa san owo bilionu N117.30 naira ati owo dola milionu 480 fun bibukun ise monamona.
Ajo naa tun gba wole pe ki won san owo toku fun sise ila meji ina 33kv ti yoo muna lo si papa oko ofurufu Nnamdi Azikwe ni Abuja. Iye owo ise naa yoo je milionu 330 naira.
Ajo naa tun ti se idasile eka merin lati se abewo si awon ibudo ile ise NIPP.
A tun gbo pe ijoba n se nnkan kan, nipa oro owo awon osise eka naa ti o m pe fun ekunwo.
Nigba ti o m ba awon oniroyin soro leyin ipade naa, Gomina Ipinle Kaduna, Namadi Sambo ti adele Gomina Ekiti, Tunji Odeyemi ati Oludari ise monamona Niger Delta Power Holding James Olutu wa pelu re, so pe ipade awon da lori lati se ayewo aseyori lori bi a se le ni ina monamona ti o moyan lori.

AWON OLOPAA PE FUN IRANLOWO

Komisona Olopaa ipinle Ekiti, iyen Chris Ola, lanaa ti pe fun iranlowo awon ara ilu lati ran won lowo lori iwadi ti o n lo lowo lori awon eeyan marun un ti won n mu ni opin ose ti o koja pelu ibon ni Ilawe-Ekiti.
Ola so fun awon oniroyin ajo Iroyin ile Naijiria (NAN), lori ero ibanisoro laipe yii pe awon olopaa mu awon eeyan naa pelu ibon ti won se ni abele, nigba ti awon olopaa n se "duro n ye o wo" awon oko ti o n koja loju popo.
O ni awon afura si naa so pe awon n lo si Ipinle Kwara lati lo pa eye lopo yanturu ni, atipe ibon ti awon ni lowo, awon ni iwe eri fun.
O wa ni pe pelu gbogbo iwadi ti awon se, won ko daruko oloselu kokan, tabi enikeni ni ipinle naa. Koda, o tun ni okan lara awon afura si naa je omo bibi ipinle Ondo, ki i se Ekiti bi won se n turo kaaakiri.
O wa ni awon eeyan naa si wa ni ahamo ni olu ago olopaa ni ipinle naa pe eni ti o ba ni oro ti o le se iranlowo fun olopaa lori oro naa ti o si je ooto, le yoju si olu ile ise olopaa.

Thursday, April 16, 2009

IRO M PA IRO FUN IRO

Asiri ti gomina ipinle P;ateau, iyen Jonah Jang pe awon ti sawari aaye kan ni bi ti won ko awon ohun ija oloro ti won tun fe fi sose ni ipinle naa si ye ko ko gbogbo eeyan lominu.
Ipnle naa ati ni pataki julo olu ilu naa Jos, ti padanu opolopo emi ati dukia ju ni bii odun meloo kan seyin, latari ija eleyameya tabi ija esin.
Koda, ninu iberu bojo ni awon ara ilu naa ati gbogbo awon eeyan to ba ni nnkan kan tabi ekeji se ninu ilu n wa ni gbogbo igba pelu iberu pe awon ko mo igba ti nnkan miran tun le sele.
Ko ye ki oro ri bee ti ko ba si pe ijoba o ki n fi taratara gbe igbese lori oro ti o ba ti jomo ti eleya meya tabi esin ko da ki won fi emi eeyan sofo ju bee lo.
Enu ya Gomina Jang pe pelu gbogbo igbese ti awon n gbe lati dekun aawo darudapo eleya meya ati elesin yii, awon kan tun n gbiyanju lati gbon owo re sinu awo ni. O ye ki o yaa lenu, sugbon ko gbodo jo loju nitori pe ninu gbogbo awon darudapo ti o n mu eleya meya ati esin dani, ti o si n mu emi awon eeyan lo, o di meloo ninu awon ajagun ta naa, ati awon to n ran won ni won wa lewon, tabi ti won ti gba idajo iku.
Pupo ninu awon darudapo yii ni won ma nse eto re daradara, ti awon to n na owo idi re si ma n je eeyan ti o nifon, leekan na lawujo wa, tabi meloo ninu awon to n na owo darudapo naa to wa lewon.
Gbogbo iwadi ti ijoba ti se lori awon oro ti o jomo darudapo esin ati eleya meya, o di melo o ti ijoba ti samulo re de oju ami. Wahala ati rogbodiyan to n tidi eleyameya ati ogun elesin sele o ni dawo duro, ayafi ti a ba to ni ijoba ti o mo bi won se n dari iru ilu to ba ni opolopo eya ati ogunlogo esin ninu.
O di igba ti a ba le ni ijoba ti o ba le je awon apaayan ni oruko esin tabi eya niya to gboopon ki won to le dekun iwa odaran yii.
O digba ti a ba le ni ijoba ti o ma gbagbo ninu orile ede Naijiria ju eya ati esin re lo nigba ti o ba kan ti ki a fi iya je odaran nipa esin ati eya.
Ni asiko odun ajinde ti o koja ni darudapo kan sele ni ipinle Niger, oro ti ko to ti e bakun gbe ni won ka sile pe o da wahala sile, awon olopaa ti ko opolopo eeyan, ti ti ojo meloo kan, won yoo ja awon die sile, leyin eyi ni ijoba yoo tun ko awon ajo kan jo lati se iwadi, leyin eyi won yoo ju iwadi won da si ibi kan, awon elese yoo ma ri n ma yan bii pe nnkan kan ko sele, bi eyi to sele nilu Jos, Kaduna ati awon ilu miran koja.

Tuesday, April 14, 2009

E PADA SENU ISE O, MIMIKO SO FUN AWON OSISE IJOBA IBILE.

Gomina Ipinle Ondo, Dokita Olusegun Mimiko ti ro awon olori osise ijoba ibile lati pada si enu ise won.
Gomina naa pe ipe naa ni ojo Aje, lati enu akowe iroyin re, Ogbeni Olabisi Kolawole.
Awon osise ijoba ibile naa ti jokoo si ile won lati ojo 16, osu keta, nigba ti awon alaga ibile ti koti ogboin si ase gomina naa ti o jawe gbele e fun won ni ojo kerin osu keta.
Isele naa ni o fa gbon mi si omi o to ti o waye laaarin Ijoba Ipinle ati awon ijoba ibile re, ti o fa ki awon osise won fi jokoo sile nitori ti erin meji ba ja, koroko ibe ni yoo fi ara ko.

E PADA SENU ISE O, MIMIKO SO FUN AWON OSISE IJOBA IBILE.

Gomina Ipinle Ondo

ERO OLOOTU

Gomina akoko ni ipinle Osun, Oloye Isiaka Adeleke ti so pe awon olowo gan an koni ni isinmi bi awon mekunnu ko ba ni awon ohun amaye derun ti o to si won.
Ooto ni o so. A i ni itiju ni o m ba awon eeyan wa ja ati ai ni iberu Oluwa lokan.
Se bi owo ti o to si gbogbo wa ni awon n mu lo si ilu oke okun lati lo wa nnkan kan tabi ekeji se, se o buru ki awon wo awokose ni awon ilu ti won nlo ki won si gbe wa si ilu ti won naa ni.
Ni aipe yii ni igba ti Aare ile Amerika, Barak Obama wole, won n wa ojutu si isoro awon eeyan, awon asofin kan daba pe ki awon ko owo lati fi se eto oro aje, sugbon Aare ni bi awon ko ba ri si oro awon mekun nu, awon n yin igbado si eyin igba ni. O dabaa pe ki awon wa owo fun awon mekun nu ki awon to dabaa miran ki o to le wole.
Ijoba ti o ba fe ni ifokan bale gbodo mo pe dodan ni ki won moju to gbogbo ara ilu lati rije rimu ki gbogbo won si wa ni alaafia.

ILE IGBIMO ASOFIN AGBA PE AWON ASOFIN IPINLE OGUN

O ti han gbangba pe awon ile igbimo asofin agba yoo darapo mo ile igbimo asofin kekere lati gba ise ile igbimo asofin ipinle Ogun se, ti won ko ba jokoo se ise ijoba won lonii gege bi ikilo ti ile igbimo asofin kekere se fun won.
Ile igbimo asofin ipinle Ogun ni a gbo pe o ye ki won yoju si awon eka ti o n se aboju to esun ati ifilo ni ojo ru, ojo keji ojo ti ile igbimo asofin kekere fun won pe awon yoo gba akoso ise won ti won ba ko lati pe aro ati odofin inu won po.
Daru dapo ti o waye laaarin Gomina Gbenga Daniel ati awon omo ile igbimo asofin kan ni o fa idi aijokoo awon ile igbimo asofin naa lati bi osu kan koja die seyin, eyi ni o fa awuye wuye ti ile igbimo asofin agba fi n da si oro abele awon asofin ipinle Ogun.
Awon asofin Ipinle Ogun ti o n tako gomina Daniel ni won ko iwe afisun si ile igbimo asofin agba, ti won gba odo asofin Iyabo Obasanjo-Bello lo, ti ile igbimo naa si taaari oro naa si ajo ti o n moju to esun ati ifilo si bere ise lori re.
Awon ile igbimo asofin kekere bere ijoko ti won latari pe awon ile asofin ipinle Ogun warun ki lati ma pada senu ise lori aba won.
A gbo pe ile igbimo asofin agba ti ko iwe pe gbogbo awon ti oro kan naa lati wa fun iyanju aawo ti o n sele naa, won ti ko iwe si agbenuso ile igbimo naa Ogbeni Tunji Egbetokun, Gomina Gbenga Daniel Awon toku ti oro tun kan ati awon agbaaagba egbe naa ni ipinle naa lati pade ni ola.

Monday, April 13, 2009

NI EKITI BAWO NI ATUNDI IBO YOO TI RI.

Ogbon kogbon lo m be ninu gbegi gbegi, ara kara lombe ninu gbenagbena, dana ogun dana ote kii se ina ire, iwa ika o to feni to ba ni Eledunmare, eyi i ga an loro to ba eto iselu to nlo lowo ni Ipinle Ekiti yii o. O da bi pe gbogbo ona ni egbe oselu PDP fe fi pada si ori aleefa yii, bakan naa ni egbe oselu AC to tako won ko sin mi edo.
O ye ki o ri bee, nitori ai duro nijo, ibeere ni ise. Sugbon o ye ki a jo yiri oro yii wo nitori gbogbo wa la jo n fe nnkan ti o dara, ohun ti o se pataki julo ti gbogbo omo eda ti Eledua da n wa naa ni igbe aye rere.
O se ni laanu pe lati bi odun kan abo seyin ti isejoba Aare Yar'adua ti bere, ko tii se abewo kaakiri ile Naijiria yanju, koda ko ti se e abewo si Ipinle Ekiti ri, o se wa je asiko atundi ibo ni Aare orile ede yii sese rojo rere lati de ipinle naa nitori pe o fe ki won di ibo won fun egbe oselu ohun pada sori aleefa.
Ka ni egbe oselu PDP ti pe aro ati odofin inu won po tele ni, ki won ti mu ni okukun dun fun enikeni ti o ba wole fun ipo ni abe asia won pe ki won se ijoba pelu eto ti won ba ni nile ti won ri pe yoo dun mo awon eeyan ninu, ko ba ti ma si pe won sese n se wahala ati inawo kiri, Oni ti fe e se bi odun kan abo, o ye ki ise ti o ba ti se sile o to fun awon eeyan lati yan pada si ipo.
Egbe oselu AC si je tuntun ni ipinle Ekiti, nitori teni to de lari a o mo ti alejo to m bo, ni Ipinle Eko ti won ti se ijoba, Fashola n gbiyanju, ti Fashola niyen, Oshiomhole ti o sese wole ni Edo, a o ti le so oun ti o fe gbese, Angeli Fayemi to m bo lona yii n ko, se yoo se rere, o ku si owo eyin oludobo Ipinle Ekiti ki e yan asoju rere fun ra yin.
Ohun ti iwe iroyin yii ka n fe ni pe, a fe ki aye rorun fun teru tomo lati gbe, ki ina oba o wa ni gbogbo asiko ti a ba fe lo, ki a ma a ri omi ti o dara mu, ki iwosan ti o peye wa fun t'eru, t'omo, ki oju ona to la geere wa ki awon eeyan ye sagbako ijamba oko loju popo latari ona ti ko dara, ki eto oro aje si kese jari, ka ri je rimu nirorun, ki abo ti o peye o siwa fun awa ati dukia wa.

IYAWO KUMUYI, OLORI IJO DEEPER LIFE DAGBERE FAYE.

Arabinrin Abiodun Kumuyi, iyawo Adari Ijo onigbagbo Deeper Life, Ojise Oluwa William F. Kumuyi ti dagbere faye.
O ku ni ojo Satide ojo kokanla ni ile re ni Ile Eko Bibeli Agbaye, ni Ayobo, Ipaja, Ilu Eko.
O ku ni omo odun 57, gege bi atejade ti o jade lati owo Akowe ijo naa ni ojo Aiku, o ku leyin aisan rampe.
A gbo pe ojise Oluwa naa mu isele iku iyawo re naa mora, enikan ni o tun kede ni ipage nla ijo won leyin wakati die ti iyawo re ku ni oju ona Eko si Ibadan.
Enikan tun ni nnkan ti kii se asa re, iwasu ti o se ni ojo Satide fun bii wakati meta.
Titi di asiko iku re, Arabinrin Kumuyi ni Alabojuto eka awon obinrin ijo naa ni ile wa Naijiria, ati gbogbo ilu ti ijo naa ni eka si kaari aye.
Arabinrin naa ni ontewe gbajugbaja iwe iroyin digi awon obinrin onigbagbo.
Oko re, Ojise Oluwa W.F. Kumuyi, Iya re pelu omo okunrin meji Jerry ati John, ati gbogbo Ijo Deeper lapapo ni o gbeyin obinrin naa.

YAR'ADUA PE FUN ATUNSE SI IPOLONGO ISE IJOBA

Aare Umar Musa Yar'adua ti pase fun awon olori eka ise ijoba lati se atuse si eka ti o n moju to bi oro se n jade labe won si igboro ati fun awon oniroyin lati le je ki awon eeyan le ba ma mo si nipa ise ti won n se.
Oludamoran pataki fun ijoba lori oro iroyin ati ipolongo, Ogbeni Olusegun Adeniyi ni o so pe ase yii waye latari pe awon alatako isejoba yii n lo anfani a i ki n pariwo ise ijoba bi o ti to ati bi o ti ye.
Oniroyin wa wo ye pe a i ki kede faraye awon ohun ti eka ijoba n gbe se n se akoba pupo ju laarin awon alatako isejoba yii to be gee ti won fi n ni ijoba ti o wa lode yii ko ja fafa.
Lati dekun a i se deede yii, ninu apileko kan ti Adeniyi ka jade, ti o da lori "Eto Ibanisoro Ninu Ijoba: Ire ati Ibi ti o wa ninu re" nibi Eti igbohun soke sodo agbaye elekeji iru re ti ile ise Timex Communications se ni Abuja ni ojo Satide ti o koja so pe ijoba ti gbabgo pe o ye ki ajosepo ma wa laarin awon osise ijoba ati awon oniroyin lati le mu ki isejoba kese jari.
Gege bi asa ibanisoro ti ijoba n gunle, ijoba ti n seto lati ri pe awon tun bo fi aaye gba ise won ki o tun bo ma han si gbangba ki awon eeyan ma ri.

ERO OLOTUU

E ku boju ojo ti ri loni o, a o jiire bi omo Yooba? Nje leyin ti e fi ojo kan ronu nipa oro awon Ijaw ni agbegbe Niger Delta ri? won o kii se omo Yooba wa.

A a! o ma se o. Bo ba ti ba oju, o di dandan ki o ba imu. A le ma wo o pe won won ki i se omo Yooba ni tooto, sugbon omo Naijiria kan naa ni gbogbo wa. Awon ni Oluwa si fi epo robi ti Naijiria fi n se oro aje jinki, e wo se ko wa tiwa subu.

Iwa idoti patapata gbaa ni awon omo ologun Ijaw wonyi nko ba wa ni orile ede yii, ti a si n wa ki awon eeyan lati ile okeere o kowo wa da ise sile nibi, awon ti a n se ni isekuse yii ko ni je ki o ya awon oludokowo lara lati wa o.

Ohun ti o yani lenu julo ni pe ijoba ti da awon eso ologun si won nigba lati maa bawon finra, e gbo se ori bibe loogun ori fifo, aya fi ki a ro o re o, ero lobe gbegiri, bi a o ba ro a ma a jona.

Iwe Iroyin yin OKIKI ko ti i pada si ori igba, sugbon iye eyin ti e ba lanfani ati ma ka iwe yi i lori ero kaari aye yii ki e ma so fun awon to ku pe OKIKI o ku o, lako la wa bi ibon.

AROKO

IROYIN APAPO

IROYIN IPINLE

IROYIN IBILE

ERO OLOTUU