Friday, August 7, 2009

IJOBA IBILE EKO, E MA DA WAHALA OFIN SILE O.

Aare egbe awon agbejoro ile Naijiria (NBA), Ogbeni Rotimi Akeredolu(SAN), ni ano ke si Minisita fun eto Idajo ati amofin agba orile ede yii, iyen Ogbeni Michael Aondoakaa(SAN), pe ki o ma da wahala ofin sile lori oro agbegbe idagbasoke ijoba ibile 37 ti ijoba Eko da sile.
Ifilo yii waye ni kete ti egbe oselu onigbale Action Congress n kilo fun AGF naa pe ki o ma si Aare Yar'Adua lona lori oro naa.
Akeredolu tun ro AGF lati sora lati da si oro ijoba apapo ati ijoba Eko, lori oro agbegbe idagbasoke ijoba ibile ti won n so. Aare NBA so eyi di mimo nigba ti o m ba awon akoroyin soro ni ano ni Ilu Eko.
Laipe yii ni Aare YAr'adua pase pe ki Gomina Eko, Raji Fashola da awon agbegbe idagbasoke ijoba ibile 37 ti o da sile nu, ki o doju ko 20 ti o wa tele tabi ki awon doju so.
Sugbon Gomina Fashola fesi pe oun ko ni pada si ijoba ibile 20, nitori 37 ti awon da sile wa ni ibamu pelu ofin.
A gbo pe Yar'adua dari leta Fashola si Aondoakaa fun imoran bi won yoo se fi owo ofin mu ijoba Eko.
Ni tire, AGF so ni ojoru ti o koja pe ki Eko pada si ijoba ibile 20, koda oun ko ti e wo leta re nitori pe gomina Fashola kan n gun lori etanje ni.
Akeredolu wa tako Aondoakaa pe idi ti awon agbejoro fi n da si ni idajo ile ejo giga ti ga julo ni orile ede yii lori ejo naa.
O ni "e kilo fun AGF ki o ma da wahala oro ofin sile ni orile ede yii.
"Amofin agba ni AGF, amofin agba si ni Gomina naa.
"ma a gba AGF ni imoran lati sora lati da si oro naa nitori ofin ti o gbe lori.
" O ye ki o mo pe Fashola o ni ki owo re bo gege lati ko iwe si ohun ti ko ba si pe o mo ipo re gege bi agba asofin.
O ni ti leta ba wa lati owo gomina miran ti ko ki n se amofin, tabi lati owo loya kekere, o ni AGF le fi owo yepere mu, sugbon ki i se leta ti o wa lati owo agba oje idi ise ofin ti o tun fe je oga si e ni o ma ni o, o ni yewo.
"Agba amofin ni Fashola ti o si ti se daradara nidi ise ofin.
"Si idi eyi, ti eeyan be e ba ko leta, kiise leta iru won ni wa ni o ni ka, maa ro AGF lati yara lo ka iwe naa ki o si samulo anfani inu re, ki o si je ki o wulo fun."
Akeredolu wa ro AGF lati ma du mahuru mo gomina ipinle kankan, o ni ohun kan pataki ti o ye ki o se ni lati to ile ejo giga Supreme court lo lati lo yiri idajo won lori oro naa wo.

Sunday, June 28, 2009

ISODOMO: A O NI SANWO ERONJA OLORO FUN YIN O -- IJOBA APAPO.

Ijiba apapo ti kede pe awon ologun ijoba ti o n wa ko pelu awon ologun ijaw yoo sinmi die ti o ba di ojo kejo osu kejo fun osu meji (ojo 60), lati le je ki awon ti won ti ronu piwada ninu awon ologun ijaw naa wa fun isodomo ati aforiji bi Aare Umaru Yar'adua se so ni ose ti o koja.
Ijoba wa fi kun oro re wipe awon ko ni san owo fun awon nnkan ija oloro ti awon ba gba lowo won, awon kan fe gba awon nnkan wonyi kuro lowo won lati so won di omo ni.
Laaarin ojo 60 yii, awon eso ologun ijoba yoo ja nigba ti awon kan ba koju won tabi ti won ba kolu agba epo nikan ni o.
Ni ile ijoba ni Abuja, awon ajo to n moju to eto isodomo naa tun salaye fun awon oniroyin pe olori awon MEND iyen Henry Okah le ri itusile ti o ba gba lati tele ilana isodomo. Ajo naa tu ni oruko awon otoku ilu ti o wa ninu iwe awon ologun ijaw naa, ti won n nawo le won lori, awon naa le ri aforiji ti won ba ti gba lati dekun iwa ibaje bee.
Alaga Ajo naa ti o tun je Minisita fun eto Abele, Ogagun (feyinti) Godwin Abbe, ti o ba awon oniroyin soro pelu Olori Alaabo, Ogagun ofurufu Paul Dike, Oga Agba Olopaa, Ogbeni Mike Okiro ati awon lookolooko toku ti won jo wa nibe tako aheso pe ijoba apapo yoo na to owo bilionu 50 lori eto naa.
Nigba ti o n tako aheso yii, Ogagun Abbe ni ijoba ko ti so pato pe bilionu 50 ni awon yoo na, won kan fi enu bu iye yii ni, won le na ju bee gan an lo lori oro naa.
"A o ni ra nnkan ija oloro pada, ko si owo fun nnkan ija", o so oju abe niko bee.
Dipo ki ijoba san owo awon nnkan ija oloro wonyi, ijoba ati awon ti oro kan, yoo pese igbe aye otun fun awon ajagun ta naa ni.
Abbe ni ona meta ni eto naa, akoko ni ki awon ajagun ta naa gba aabo ti ijoba fe se, eekeji, ki won lo ko nnkan ija oloro owo won sile ni agbegbe ti won ya soto ti o ba sun mo won, iketa ni siso won domo.
"Ona ti o po ni, eni ti o ba pe owo bilionu 50 ni ibere kan daba ni, o le ju be e lo," bi o ti wi , ti o tun so siwaju sii pe eto naa kan ijoba apapo, awon ijoba ibile, awon ijoba ipinle, ati awon ile ise epo ti o wa lagbegbe Niger Delta naa.
Nigba ti o n soro lori kini ipin Okah, Abbe ni "gbogbo awon akogun naa ti won nwadi lowo ni won yoo jeere. Ni ti Okah, e o ri pe won gbe pada wa sile lati ilu Afirika kan ni. A o ma kan si ijoba Angola gbogbo nnkan ti a ba se lori re.
"Titi ti eto yii yoo fi pari, yoo soro lati so pe ojo bayii ni, sugbon nnkan ti o daju ni pe ohun naa yoo jere bi awon to ku."
Agbenuso pataki fun aare lori oro eto iroyin ati ipolongo, Ogbeni Olusegun Adeniyi ti o wun naa ba won wa nibi ibanisoro naa so pe ijoba apapo nba ijoba Equatorial Guinea soro lori oro ati da Henry Okah pada sile.
Adeniyi tun ni Yar'adua ti ba awon elegbe ti Angola ati Equatorial Guinea soro tele nipa Okah.
"Nnkan ti ijoba yoo se laipe yii ni pe won yoo ran awon eeyan lo si awon ilu yii lati yanju oro ati mu pada. Leyin eyi ni won yoo nowo aabo si, ti o ba gba, won yoo jo re," bi agbenuso ijoba ti so.

IGBA OTUN DE, AYE FE YI PADA.

Igba otun ti de sile aye, e sa a wo, akoko, ni ile Amerika, won yan eeyan dudu lati di Aare ile Amerika, eyi ti won bura fun di Aare ninu osu kinni odun yii. Eyi tumo si gbigba adura ojo pipe ti awon olori alawo dudu ti n jeran iru nnkan bee, nigba ti won yan Barack Obama lati se Aare orile ede ti o lagbara julo ni agbaye.
Kayefi to tun wa sele nibe ni ti Ile Igbimo Asofin ile Amerika, ni ose to koja, ti won rawo ebe fun pe awon se owo eru ati rira tita awon eeyan ni orile ede naa ri.
Gege bi gbogbo wa ti mo, awa Afirika alawo dudu naa ni won n ra wo ebe si, nitori awa naa ni gbogbo re kangun le lori.
Boya ni eyin mo pe laaarin odun 1445 ati 1870 ti owo rira ati tita eru fi sele, o le ni milionu mewa alawo dudu omo ile Afirika ti o ba okoowo naa lo.
Leyin nnkan bi odun 233 leyin isele yii ni awon Amerika sese rojo ire ati be wa fun isele naa ti o da hila hilo sile, ti ko je ki awon omo Afirika roju raye se aye won bi won se fe ati ni iru eda ti Oluwa da won, awon oyinbo ni ko je ki a roju tu gbogbo nnkan ti a mo o se fun ra wa mo.
A ti n se ijoba wa bi ase fe, a n se okoowo asi n gbe bi ase le gbe pelu ara wa, ki won to rari wo wa laaarin. O le ni odun 400 ti won fi da wa ribo ribo, won wa n se wa bi eni pe kiise pe Oluwa jo dawa saye wa ko ipa kan tabi ekeji ni.
Sugbon, o ye ki inu wa dun ni asiko yii, pe o ti foju han gban gba, gban gba bayii pe won ti mo pe awon se si eledaa wa, won si ti toro aforiji, awon omo wa si ti n ba won jokoo se ijoba leleka o jeka ni orile ede agbaye kaaakiri, a n ba won kopa ninu iwe a si n bori ju won lo nigba miran, a n ba won se ere idaraya orisirisi, a si n je wo agbara ti Oluwa fi jinki wa pe okan naa ni wa, awo lasan ni o yato, awa kii se obo.

Sunday, June 14, 2009

JUNE 12 KO SE E GBAGBE O.

Awon Ajaja n Gbara ati awon Egbe Ajafeto ti se opolopo eto lati fi han pe ayajo ojo June 12, ko parun, ati pe ki ijoba ye e ka Ojo 29 Osu Ebibi (May 29), ni ojo isami iselu fun wa mo, June 12, gan ni ojo ti o ye ki won ya soto ni ile Naijiria fun ayajo isami iselu.
Ni tooto, ojo mejeeji yii ni ami ni orile ede wa, sugbon awon ajajangbara n taku se, pe ko si ojo miran ti a se eto idibo ti o kese jari julo ni ile wa Naijiria bi ko ba se June 12, 1993.
Won fe ki ijoba mo ojo yii gege bi ojo ti a se eto idibo ti o dangajia julo ni ile Naijiria, ki won si ye eni ti won ni o yege ibo naa ti ko si ri opa ase gba Oloye Moshood Olawale Kasimawo Abiola si la ti fi mo riri ise gidi ti o se.
Awon egbe ajaja n gbara ati ajafe to bi CLO, CDRP, CDDR, ati awon toku, se ayeye isami naa ni Eko, Abuja ati Osogbo lati sami june 12.
Egbe oselu Onigbale (AC), mu ileri won se lati ba won kopa ninu gbogbo eto ti won ba se lati sami ojo naa.
Humphrey Nwosu, ti o je alaga eto idibo nigba naa bee re pe ojo wo ni a tun le pe ni ayajo ojo ti a se eto idibo ti o kese jari julo ni ile wa Naijiria, o ni ojo june 12 ni gbogbo omo Naijiria ni tile toko so eleyameya nu, won ko ti e wo esin, won ko si wo ti asa, won ko si wo ti ede tabi ipinle ti won si huwa bi awon eeyan ilu olaju bi America tabi Britain.
Lai Mohammed ti o je alukoro egbe Onigbale (AC) lapapo naa so wi pe June 12 ti di apeere fun ile Naijiria gege bi ojo ti a se eto idibo ti o kese jari julo. Ni ojo naa, eeyan kan ibo kan ni ti ko si ni se pelu esin tabi eya, ojo yii gan an ni awon eeyan yan Aare won funra won ninu ibo ti o rorun julo bi o ti wi.
Mohammed ni egbe onigbale n fe ki won ya ojo naa soto fun ayajo ojo iselu eyi ni o le je ki ijoba ti wa n ti wa o tu bo tewon si. O wa ni, ni gbogbo igba ti ijoba ko ba ti fi aaye gba ojo yii gege bi ayajo ojo iselu, awon eeyan ti won lodi si ijoba ti wa n ti wa naa ni yoo si ma yan awon eeyan je ti won ko fi ni le yan adari ti o je ti won.
"Awon ijoba ti o wa lode ni asiko yii n se nnkan ti won fe ni, nitori kii se awon eeyan funra won ni won yan won, won ko si le jabo fun won. Ni awon Ipinle Eko ati Edo ti o je pe awon eeyan ni o yan ijoba won fun ra won, awon gomina won n jabo fun won , won si ti di arikose fun awon to ku fun isejoba rere."
Gomina meji Ipinle Eko ati Ogun ilu Bashorun Abiola fun awon osise won ni isinmi lati sami ayajo ojo naa, Fashola ni ayajo ojo naa gan an ni ojo iselu to si julo ni ile wa Naijiria.

Friday, June 5, 2009

A TO RO GAAAFARA.

Gbogbo eyin ti e n ka awon iroyin wa, a dupe fun afokan tan yin, a n se awon atunse kan lowo ti o le mu iroyin yii kun si ati lati le ni itumo to bi a ti se fe si ati ki eyin naa le gbadun re dara dara.
Iroyin yoruba meta ni a ni ati ti oyinbo kan. Ekinni, ni OKIKI LEDE YORUBA, eyi ti e n ri ka lori www.okikinewspaers.blogspot.com, eekeji ni AWOKO OGA EDE, ti e o ma ri ka ni www.awokoogaede.blogspot.com, nigba ti eketa si je, IROYIN OOJO, ti e ma ri ni ori www.iroyinoojo.blogspot.com , ekerin re ni ti ede oyinbo, CULTURAL TIPS, ti e ma ri ni ori www.culturaltips.blogspot.com .
A ti wa se atunse si ki o ma ba ma jo ara won, OKIKI yoo ma gbe itan gbuuru jade lori awon isele gbankan gbii. (OKIKI will bring features on events and current affairs), nigba ti AWOKO OGA EDE yooma so awon oku iroyin di alaaye, fun iranti awon agbalagba, ati fun eko fun awon ewe. (AWOKO OGA EDE published historically refreshing stories), nigba ti IROYIN OOJO ni yoo ma gbe awon iroyin ojoojumo jade bi o ti n sele gan an ni orile ede wa.(IROOYIN OOJO, (DAILY NEWS) , ill published daily news as it unfold on a daily basis. Eyi ti o gbeyin ni CULTURAL TIPS, eyi ni yoo ma ko ni pa asa ati ise ile wa, (CULTURAL TIPS, will talk and discussed culture and heritage of our people, culture news and all that has to do with culture. E KAA BO SI AYE WA. (WELCOME TO OUR WORLD).

Wednesday, May 27, 2009

70,000 OMO NAIJIRIA NI O BERE FUN IWE IGBELU OYINBO LODUN TO KOJA.

Asoju Ijoba Orile ede America ni orile ede wa Naijiria, ti so pe eeyan bi 70,000 omo orile ede yii ni o kopa ninu iwe igbelu awon ti won se ni odun to koja, o wa woye pe yoo tun fe po jube lo ti odun 2009 yii ba ma fi pari.
Asoju ijoba America naa, iyen Ogbeni Robin Sanders ni o sobe nilu Abuja nigba ti o m ba awon oniroyin soro.
O ni ninu aduru awon ti o yoju, awon fun eeyan 58,000 ni iwe pe ki won lo gbe ilu awon.

AWON OLUKO ILE EKO IJOBA IYEN 'UNITY' BERE IYANSE LODI LENII.

Awon oluko ile iwe koleji ijoba apapo yoo bere iyanse lodi gbere lenii, latari oro ti o ni se pelu oro osise.
Atejade kan lati owo akowe agba awon osise agba ile ise ijoba ti ile naijiria, ogbeni Solomon Onaghinon, ro awon obi ki lo ko awon omo won kuro ni ile eko kiakia.
Atejade naa se deede pelu ipade ti awon eka eto eko ni ile igbimo asofin agba pelu minisita funeto eko , iye Dokita Sam Egwu se lori iyanse lodi sora e ti awon oluko yunifasiti se.
Iyanse lodi awon oluko ile iwe giga unity ti ijoba da lori pe ijoba ko tete fesi si awon nkan ti won n beere fun leyin ogbon ojo ti won fun won.
Awon oluko naa ti koko lo fun iyanse lodi ni ojo keje osu kinni odun, latari pe ijoba fe ta awon ile iwe fun aladani. Lara awon ehonu won tun ni pipin nnkan bi 3,000 awon elegbe won kuro ni aaye ti won wa lo si ibomiran ki asiko ti o ye ki won lo ni aaye ti won wa to, to, paapa julo awon ti won je asoju awon osise naa.
Ajo osise naa ti won so eyi tako oro ajoso awon ti o wa ye ni odun 2006, bakan naa tun ni aisa ile 15 fun awon ti ko si akamo ile eko unity ni ilu Abuja.

ENI NI AYAJO OJO AWON EWE.

O daju saka, awon ewe yoo tun bo sita lenii, lati lo se ayeye ajodun odun awon ewe bi won ti n se lodoodun, awon ewe yii naa sa ni ewa awon obi, ati ojo ola gbogbo orile ede kaakiri agbaye.
Awon ewe yii yoo bo siwaju awon gomina kaaakiri ipinle, ati alaga ijoba ibile kaakiri gbogbo orile ede Naijiria naa lenii, o daju inu awon gomina ati awon alaga ibile naa yoo si dun pe awon ogoweere yan niwaju won.
Leyin eyi, won yoo sa awon die ti won je omo eeyan pataki lawujo, koda ti awon ko tile yan ninu oorun bi awon omo talaka egbe won soto, won yoo se apeje fun won, o ba tan, odun pari, o tun di odun to m bo.
Awon gomina ati awon alaga kansu yii yoo sa awon omo olomo soorun, awon yoo wa labe iboji, won yoo ma ka iwe apile ko to je kiki ileri iro fun awon omo yii pe awon yoo se, sugbon ti a ba tu idi awon iroyin kayeefi yi wo, iro funfun ni a o ba nibe, agbara ki ni awon ogooweere yii yo sa lati ni ki won dake ki won ye paro fun awon.
Oju kii ti e ti awon ijoba wa lati je ki awon omo olomo ti o n wa fi ebi panu ma yan niwaju won, o di meloo ninu awon ijoba ti o ti koja oloogun tabi oloselu ti ko ti fi oju awon omo yii rare ri, eto eko ti mehe tan ni orile ede yii, awon to ba rije die, ile eko aladani ni won n ko awon omo won lo, e lo wo awon ile eko ijoba, ko si eyi ti o leero mo, nitori a i nigbagbo awon obi ninu eto eko ijoba mo ni.
Gbogbo eeyan ti awon omo wonyii ba fi inu ofifo yan niwaju yin, ti esi ntan won je, ti e n fi ojo iwaju won rare, ori won yoo bi yin o, o tan le nu o ku sikun, aabo oro la n so fun omoluabi ti o ba de inu re yoo di odindi.

Friday, May 22, 2009

GBENGA DANIEL FE TUN ONA OTA SE.

Gomina Ipinle Ogun, oloye Gbenga Daniel ti pase pe ki awon ajo ti o tun ona se(OGROMA) lo se ise gbogbo ona ti o wa ni agbegbe afara ti ijoba apapo se ti ni Sango ni ano.
Ise afara naa ti ise ijoba Olusegun Obasanjo bere ki o to fi ipo sile ni a gbo pe won ti pati bi odun meji seyin bayi, eyi ti o ti n nko laaasigbo ba awon oloko ati awon olugbe Sango.
Atejade ti o jade lati owo agbenuso gomina iyen ogbeni Adegbenro Adebanjo so pe ase yii wa lati ibi ipade apapo ti awon isejoba ipinle naa latari ati dekun iya ti o n je awon awako ati ara ilu.
Ninu atejade naa, o tun so siwaju pe ajo naa kanpa pe ki OGROMA se egbegbe afara naa mejeeji ati gbogbo agbegbe ona ti o yii ka lati le ri pe o rorun fun oko lati rin geere.

E SORA FOGUN ABELE ELEEKEJI

Ti ero iwe iroyin yii ba jo ti gbogbo onkawe yii patapata, e ni ti o ba sun mo awon ijoba, ki o so fun won ki won si n mi edo. Gbogbo ipinle kookan lorile ede yii ni Oluwa Oba adaniwaye fi n kan, kan tabi ekeji se ohun alumoni fun un, ki o ma je anfani fun won, bee naa si ni o se kaaakiri agbanla aye ibi ti o da awon eeyan, alujonu ati eranko toku sii.
Awon oyinbo amunisin to mu ile alawo dudu leru lemi ri bawi, ni se ni won da luuru po mo sapa, won o je ki a rin pade, ka ye ara wa wo boya a le ba ara wa se ki won to so oro di ojo to ro, to wa ko eyele po mo adiye. Ta ni ko mo pe eyele pelu adiye kii se egbe rara.
Oyinbo ti lo tan, won ti se ase mase, n je o wa ye ki awa ti won se bi won ti fe yii, naa ma tun le da inu ro bi. Awa ko fara mo iwa ti awon omo Ijaw n wu, be e si a ko fe ki awon ologun pa enikeni mo, ita eje sile ko ye wa lorile ede yii, ogun ko se enikeni lanfani, e je ki a fi pele kutu yanju oro ti o ba wa laaarin ara wa ni.

Sunday, May 17, 2009

AWON OLOPAA FAKO YO

Awon olopaa ni olu ilu NAijiria, ni Abuja, fa ako yo ni opin ose nigba ti won koju awon igaara olosa, ti won si pa merin ninu won, ti won si tun mu meji ti won ba ibon ak47, lowo won.
Nigba ti o m gbe oriyin fun awon akoni naa, Oga Olopaa Yan yan, Sir Mike Okiro ro awon isori olopaa to ku naa, lati tun bo mura si kikoju awon janduku naa ki a le, le ole kuro lawujo wa.

IJAMBA INA L'EKOO

Awon olugbe ipinle Eko ji lati gbo iroyin ijamba oko epo robi ti o jona ni ano, iyen 16/5/2009 ti o si pa awako ati omo eyin oko naa, ti won jona gbuugbu, ti ko si eni ti o le da won mo.
Isele naa ti o sele ni oju ona marose papa oko ofurufu Muritala Muhammed ni a gbo pe ogooro awon ero ni o ro lo si ibe.
Sugbon, ki awon olopaa ati awon osise panopano to de ibe, luputu ti hu, akuko ti ko leyin awon ti ijamba ina naa sele si.

FASHOLA SE BEBE FUN AWON ODO

Ni ojo bo, ti o koja, iyen 14/5/2009, Gomina Raji Fashola (Amofin Agba), ti Ile Eko, gbe igbese agba yanu nipa riranti awon ewe ninu isakoso re, o da awon odo pada si igba atijo ti won n se egbe odo wosowoso.
Igbese yii dara nitori ona kan pataki re lati dekun iwa odaran lowo awon omode, nitori irufe awon egbe yii ma ngbogun ti iwa ibaje lawujo ni.
Egbe odo wosowoso marun ni Gomina Fashola safihan re, awon ni egbe Boys Scout, egbe Sheriff Guards, egbe Boys Brigade, egbe Girls Guide ati egbe Red Cross.
A ro gbogbo gomina ipinle to ku lati gbe iru igbese gban kan gbi i naa ninu isakoso won, nitori ona kan re e lati kowo omo awon odo bo aso.

Wednesday, April 22, 2009

IJOBA N GBE IGBESE LORI INA MONAMONA

Ijoba ti bu owo lu ise ero amuna wa lanaa, pelu owo bilionu meedogun(n15bn), eyi ja si pe laipe, ina monamona yoo yato si ti ateyinwa.
Ajo ti o n ri si ipese ina monamona aladani, iyen (National Independent Power Project), ti igbakeji Aare Goodluck Jonathan je alaga re ni won ti gba ise naa wole.
Gbigba wole yii waye ni deede osu kan ti ajo naa san owo bilionu N117.30 naira ati owo dola milionu 480 fun bibukun ise monamona.
Ajo naa tun gba wole pe ki won san owo toku fun sise ila meji ina 33kv ti yoo muna lo si papa oko ofurufu Nnamdi Azikwe ni Abuja. Iye owo ise naa yoo je milionu 330 naira.
Ajo naa tun ti se idasile eka merin lati se abewo si awon ibudo ile ise NIPP.
A tun gbo pe ijoba n se nnkan kan, nipa oro owo awon osise eka naa ti o m pe fun ekunwo.
Nigba ti o m ba awon oniroyin soro leyin ipade naa, Gomina Ipinle Kaduna, Namadi Sambo ti adele Gomina Ekiti, Tunji Odeyemi ati Oludari ise monamona Niger Delta Power Holding James Olutu wa pelu re, so pe ipade awon da lori lati se ayewo aseyori lori bi a se le ni ina monamona ti o moyan lori.

AWON OLOPAA PE FUN IRANLOWO

Komisona Olopaa ipinle Ekiti, iyen Chris Ola, lanaa ti pe fun iranlowo awon ara ilu lati ran won lowo lori iwadi ti o n lo lowo lori awon eeyan marun un ti won n mu ni opin ose ti o koja pelu ibon ni Ilawe-Ekiti.
Ola so fun awon oniroyin ajo Iroyin ile Naijiria (NAN), lori ero ibanisoro laipe yii pe awon olopaa mu awon eeyan naa pelu ibon ti won se ni abele, nigba ti awon olopaa n se "duro n ye o wo" awon oko ti o n koja loju popo.
O ni awon afura si naa so pe awon n lo si Ipinle Kwara lati lo pa eye lopo yanturu ni, atipe ibon ti awon ni lowo, awon ni iwe eri fun.
O wa ni pe pelu gbogbo iwadi ti awon se, won ko daruko oloselu kokan, tabi enikeni ni ipinle naa. Koda, o tun ni okan lara awon afura si naa je omo bibi ipinle Ondo, ki i se Ekiti bi won se n turo kaaakiri.
O wa ni awon eeyan naa si wa ni ahamo ni olu ago olopaa ni ipinle naa pe eni ti o ba ni oro ti o le se iranlowo fun olopaa lori oro naa ti o si je ooto, le yoju si olu ile ise olopaa.

Thursday, April 16, 2009

IRO M PA IRO FUN IRO

Asiri ti gomina ipinle P;ateau, iyen Jonah Jang pe awon ti sawari aaye kan ni bi ti won ko awon ohun ija oloro ti won tun fe fi sose ni ipinle naa si ye ko ko gbogbo eeyan lominu.
Ipnle naa ati ni pataki julo olu ilu naa Jos, ti padanu opolopo emi ati dukia ju ni bii odun meloo kan seyin, latari ija eleyameya tabi ija esin.
Koda, ninu iberu bojo ni awon ara ilu naa ati gbogbo awon eeyan to ba ni nnkan kan tabi ekeji se ninu ilu n wa ni gbogbo igba pelu iberu pe awon ko mo igba ti nnkan miran tun le sele.
Ko ye ki oro ri bee ti ko ba si pe ijoba o ki n fi taratara gbe igbese lori oro ti o ba ti jomo ti eleya meya tabi esin ko da ki won fi emi eeyan sofo ju bee lo.
Enu ya Gomina Jang pe pelu gbogbo igbese ti awon n gbe lati dekun aawo darudapo eleya meya ati elesin yii, awon kan tun n gbiyanju lati gbon owo re sinu awo ni. O ye ki o yaa lenu, sugbon ko gbodo jo loju nitori pe ninu gbogbo awon darudapo ti o n mu eleya meya ati esin dani, ti o si n mu emi awon eeyan lo, o di meloo ninu awon ajagun ta naa, ati awon to n ran won ni won wa lewon, tabi ti won ti gba idajo iku.
Pupo ninu awon darudapo yii ni won ma nse eto re daradara, ti awon to n na owo idi re si ma n je eeyan ti o nifon, leekan na lawujo wa, tabi meloo ninu awon to n na owo darudapo naa to wa lewon.
Gbogbo iwadi ti ijoba ti se lori awon oro ti o jomo darudapo esin ati eleya meya, o di melo o ti ijoba ti samulo re de oju ami. Wahala ati rogbodiyan to n tidi eleyameya ati ogun elesin sele o ni dawo duro, ayafi ti a ba to ni ijoba ti o mo bi won se n dari iru ilu to ba ni opolopo eya ati ogunlogo esin ninu.
O di igba ti a ba le ni ijoba ti o ba le je awon apaayan ni oruko esin tabi eya niya to gboopon ki won to le dekun iwa odaran yii.
O digba ti a ba le ni ijoba ti o ma gbagbo ninu orile ede Naijiria ju eya ati esin re lo nigba ti o ba kan ti ki a fi iya je odaran nipa esin ati eya.
Ni asiko odun ajinde ti o koja ni darudapo kan sele ni ipinle Niger, oro ti ko to ti e bakun gbe ni won ka sile pe o da wahala sile, awon olopaa ti ko opolopo eeyan, ti ti ojo meloo kan, won yoo ja awon die sile, leyin eyi ni ijoba yoo tun ko awon ajo kan jo lati se iwadi, leyin eyi won yoo ju iwadi won da si ibi kan, awon elese yoo ma ri n ma yan bii pe nnkan kan ko sele, bi eyi to sele nilu Jos, Kaduna ati awon ilu miran koja.

Tuesday, April 14, 2009

E PADA SENU ISE O, MIMIKO SO FUN AWON OSISE IJOBA IBILE.

Gomina Ipinle Ondo, Dokita Olusegun Mimiko ti ro awon olori osise ijoba ibile lati pada si enu ise won.
Gomina naa pe ipe naa ni ojo Aje, lati enu akowe iroyin re, Ogbeni Olabisi Kolawole.
Awon osise ijoba ibile naa ti jokoo si ile won lati ojo 16, osu keta, nigba ti awon alaga ibile ti koti ogboin si ase gomina naa ti o jawe gbele e fun won ni ojo kerin osu keta.
Isele naa ni o fa gbon mi si omi o to ti o waye laaarin Ijoba Ipinle ati awon ijoba ibile re, ti o fa ki awon osise won fi jokoo sile nitori ti erin meji ba ja, koroko ibe ni yoo fi ara ko.

E PADA SENU ISE O, MIMIKO SO FUN AWON OSISE IJOBA IBILE.

Gomina Ipinle Ondo

ERO OLOOTU

Gomina akoko ni ipinle Osun, Oloye Isiaka Adeleke ti so pe awon olowo gan an koni ni isinmi bi awon mekunnu ko ba ni awon ohun amaye derun ti o to si won.
Ooto ni o so. A i ni itiju ni o m ba awon eeyan wa ja ati ai ni iberu Oluwa lokan.
Se bi owo ti o to si gbogbo wa ni awon n mu lo si ilu oke okun lati lo wa nnkan kan tabi ekeji se, se o buru ki awon wo awokose ni awon ilu ti won nlo ki won si gbe wa si ilu ti won naa ni.
Ni aipe yii ni igba ti Aare ile Amerika, Barak Obama wole, won n wa ojutu si isoro awon eeyan, awon asofin kan daba pe ki awon ko owo lati fi se eto oro aje, sugbon Aare ni bi awon ko ba ri si oro awon mekun nu, awon n yin igbado si eyin igba ni. O dabaa pe ki awon wa owo fun awon mekun nu ki awon to dabaa miran ki o to le wole.
Ijoba ti o ba fe ni ifokan bale gbodo mo pe dodan ni ki won moju to gbogbo ara ilu lati rije rimu ki gbogbo won si wa ni alaafia.

ILE IGBIMO ASOFIN AGBA PE AWON ASOFIN IPINLE OGUN

O ti han gbangba pe awon ile igbimo asofin agba yoo darapo mo ile igbimo asofin kekere lati gba ise ile igbimo asofin ipinle Ogun se, ti won ko ba jokoo se ise ijoba won lonii gege bi ikilo ti ile igbimo asofin kekere se fun won.
Ile igbimo asofin ipinle Ogun ni a gbo pe o ye ki won yoju si awon eka ti o n se aboju to esun ati ifilo ni ojo ru, ojo keji ojo ti ile igbimo asofin kekere fun won pe awon yoo gba akoso ise won ti won ba ko lati pe aro ati odofin inu won po.
Daru dapo ti o waye laaarin Gomina Gbenga Daniel ati awon omo ile igbimo asofin kan ni o fa idi aijokoo awon ile igbimo asofin naa lati bi osu kan koja die seyin, eyi ni o fa awuye wuye ti ile igbimo asofin agba fi n da si oro abele awon asofin ipinle Ogun.
Awon asofin Ipinle Ogun ti o n tako gomina Daniel ni won ko iwe afisun si ile igbimo asofin agba, ti won gba odo asofin Iyabo Obasanjo-Bello lo, ti ile igbimo naa si taaari oro naa si ajo ti o n moju to esun ati ifilo si bere ise lori re.
Awon ile igbimo asofin kekere bere ijoko ti won latari pe awon ile asofin ipinle Ogun warun ki lati ma pada senu ise lori aba won.
A gbo pe ile igbimo asofin agba ti ko iwe pe gbogbo awon ti oro kan naa lati wa fun iyanju aawo ti o n sele naa, won ti ko iwe si agbenuso ile igbimo naa Ogbeni Tunji Egbetokun, Gomina Gbenga Daniel Awon toku ti oro tun kan ati awon agbaaagba egbe naa ni ipinle naa lati pade ni ola.

Monday, April 13, 2009

NI EKITI BAWO NI ATUNDI IBO YOO TI RI.

Ogbon kogbon lo m be ninu gbegi gbegi, ara kara lombe ninu gbenagbena, dana ogun dana ote kii se ina ire, iwa ika o to feni to ba ni Eledunmare, eyi i ga an loro to ba eto iselu to nlo lowo ni Ipinle Ekiti yii o. O da bi pe gbogbo ona ni egbe oselu PDP fe fi pada si ori aleefa yii, bakan naa ni egbe oselu AC to tako won ko sin mi edo.
O ye ki o ri bee, nitori ai duro nijo, ibeere ni ise. Sugbon o ye ki a jo yiri oro yii wo nitori gbogbo wa la jo n fe nnkan ti o dara, ohun ti o se pataki julo ti gbogbo omo eda ti Eledua da n wa naa ni igbe aye rere.
O se ni laanu pe lati bi odun kan abo seyin ti isejoba Aare Yar'adua ti bere, ko tii se abewo kaakiri ile Naijiria yanju, koda ko ti se e abewo si Ipinle Ekiti ri, o se wa je asiko atundi ibo ni Aare orile ede yii sese rojo rere lati de ipinle naa nitori pe o fe ki won di ibo won fun egbe oselu ohun pada sori aleefa.
Ka ni egbe oselu PDP ti pe aro ati odofin inu won po tele ni, ki won ti mu ni okukun dun fun enikeni ti o ba wole fun ipo ni abe asia won pe ki won se ijoba pelu eto ti won ba ni nile ti won ri pe yoo dun mo awon eeyan ninu, ko ba ti ma si pe won sese n se wahala ati inawo kiri, Oni ti fe e se bi odun kan abo, o ye ki ise ti o ba ti se sile o to fun awon eeyan lati yan pada si ipo.
Egbe oselu AC si je tuntun ni ipinle Ekiti, nitori teni to de lari a o mo ti alejo to m bo, ni Ipinle Eko ti won ti se ijoba, Fashola n gbiyanju, ti Fashola niyen, Oshiomhole ti o sese wole ni Edo, a o ti le so oun ti o fe gbese, Angeli Fayemi to m bo lona yii n ko, se yoo se rere, o ku si owo eyin oludobo Ipinle Ekiti ki e yan asoju rere fun ra yin.
Ohun ti iwe iroyin yii ka n fe ni pe, a fe ki aye rorun fun teru tomo lati gbe, ki ina oba o wa ni gbogbo asiko ti a ba fe lo, ki a ma a ri omi ti o dara mu, ki iwosan ti o peye wa fun t'eru, t'omo, ki oju ona to la geere wa ki awon eeyan ye sagbako ijamba oko loju popo latari ona ti ko dara, ki eto oro aje si kese jari, ka ri je rimu nirorun, ki abo ti o peye o siwa fun awa ati dukia wa.

IYAWO KUMUYI, OLORI IJO DEEPER LIFE DAGBERE FAYE.

Arabinrin Abiodun Kumuyi, iyawo Adari Ijo onigbagbo Deeper Life, Ojise Oluwa William F. Kumuyi ti dagbere faye.
O ku ni ojo Satide ojo kokanla ni ile re ni Ile Eko Bibeli Agbaye, ni Ayobo, Ipaja, Ilu Eko.
O ku ni omo odun 57, gege bi atejade ti o jade lati owo Akowe ijo naa ni ojo Aiku, o ku leyin aisan rampe.
A gbo pe ojise Oluwa naa mu isele iku iyawo re naa mora, enikan ni o tun kede ni ipage nla ijo won leyin wakati die ti iyawo re ku ni oju ona Eko si Ibadan.
Enikan tun ni nnkan ti kii se asa re, iwasu ti o se ni ojo Satide fun bii wakati meta.
Titi di asiko iku re, Arabinrin Kumuyi ni Alabojuto eka awon obinrin ijo naa ni ile wa Naijiria, ati gbogbo ilu ti ijo naa ni eka si kaari aye.
Arabinrin naa ni ontewe gbajugbaja iwe iroyin digi awon obinrin onigbagbo.
Oko re, Ojise Oluwa W.F. Kumuyi, Iya re pelu omo okunrin meji Jerry ati John, ati gbogbo Ijo Deeper lapapo ni o gbeyin obinrin naa.

YAR'ADUA PE FUN ATUNSE SI IPOLONGO ISE IJOBA

Aare Umar Musa Yar'adua ti pase fun awon olori eka ise ijoba lati se atuse si eka ti o n moju to bi oro se n jade labe won si igboro ati fun awon oniroyin lati le je ki awon eeyan le ba ma mo si nipa ise ti won n se.
Oludamoran pataki fun ijoba lori oro iroyin ati ipolongo, Ogbeni Olusegun Adeniyi ni o so pe ase yii waye latari pe awon alatako isejoba yii n lo anfani a i ki n pariwo ise ijoba bi o ti to ati bi o ti ye.
Oniroyin wa wo ye pe a i ki kede faraye awon ohun ti eka ijoba n gbe se n se akoba pupo ju laarin awon alatako isejoba yii to be gee ti won fi n ni ijoba ti o wa lode yii ko ja fafa.
Lati dekun a i se deede yii, ninu apileko kan ti Adeniyi ka jade, ti o da lori "Eto Ibanisoro Ninu Ijoba: Ire ati Ibi ti o wa ninu re" nibi Eti igbohun soke sodo agbaye elekeji iru re ti ile ise Timex Communications se ni Abuja ni ojo Satide ti o koja so pe ijoba ti gbabgo pe o ye ki ajosepo ma wa laarin awon osise ijoba ati awon oniroyin lati le mu ki isejoba kese jari.
Gege bi asa ibanisoro ti ijoba n gunle, ijoba ti n seto lati ri pe awon tun bo fi aaye gba ise won ki o tun bo ma han si gbangba ki awon eeyan ma ri.

ERO OLOTUU

E ku boju ojo ti ri loni o, a o jiire bi omo Yooba? Nje leyin ti e fi ojo kan ronu nipa oro awon Ijaw ni agbegbe Niger Delta ri? won o kii se omo Yooba wa.

A a! o ma se o. Bo ba ti ba oju, o di dandan ki o ba imu. A le ma wo o pe won won ki i se omo Yooba ni tooto, sugbon omo Naijiria kan naa ni gbogbo wa. Awon ni Oluwa si fi epo robi ti Naijiria fi n se oro aje jinki, e wo se ko wa tiwa subu.

Iwa idoti patapata gbaa ni awon omo ologun Ijaw wonyi nko ba wa ni orile ede yii, ti a si n wa ki awon eeyan lati ile okeere o kowo wa da ise sile nibi, awon ti a n se ni isekuse yii ko ni je ki o ya awon oludokowo lara lati wa o.

Ohun ti o yani lenu julo ni pe ijoba ti da awon eso ologun si won nigba lati maa bawon finra, e gbo se ori bibe loogun ori fifo, aya fi ki a ro o re o, ero lobe gbegiri, bi a o ba ro a ma a jona.

Iwe Iroyin yin OKIKI ko ti i pada si ori igba, sugbon iye eyin ti e ba lanfani ati ma ka iwe yi i lori ero kaari aye yii ki e ma so fun awon to ku pe OKIKI o ku o, lako la wa bi ibon.

AROKO

IROYIN APAPO

IROYIN IPINLE

IROYIN IBILE

ERO OLOTUU