Wednesday, May 27, 2009

70,000 OMO NAIJIRIA NI O BERE FUN IWE IGBELU OYINBO LODUN TO KOJA.

Asoju Ijoba Orile ede America ni orile ede wa Naijiria, ti so pe eeyan bi 70,000 omo orile ede yii ni o kopa ninu iwe igbelu awon ti won se ni odun to koja, o wa woye pe yoo tun fe po jube lo ti odun 2009 yii ba ma fi pari.
Asoju ijoba America naa, iyen Ogbeni Robin Sanders ni o sobe nilu Abuja nigba ti o m ba awon oniroyin soro.
O ni ninu aduru awon ti o yoju, awon fun eeyan 58,000 ni iwe pe ki won lo gbe ilu awon.

AWON OLUKO ILE EKO IJOBA IYEN 'UNITY' BERE IYANSE LODI LENII.

Awon oluko ile iwe koleji ijoba apapo yoo bere iyanse lodi gbere lenii, latari oro ti o ni se pelu oro osise.
Atejade kan lati owo akowe agba awon osise agba ile ise ijoba ti ile naijiria, ogbeni Solomon Onaghinon, ro awon obi ki lo ko awon omo won kuro ni ile eko kiakia.
Atejade naa se deede pelu ipade ti awon eka eto eko ni ile igbimo asofin agba pelu minisita funeto eko , iye Dokita Sam Egwu se lori iyanse lodi sora e ti awon oluko yunifasiti se.
Iyanse lodi awon oluko ile iwe giga unity ti ijoba da lori pe ijoba ko tete fesi si awon nkan ti won n beere fun leyin ogbon ojo ti won fun won.
Awon oluko naa ti koko lo fun iyanse lodi ni ojo keje osu kinni odun, latari pe ijoba fe ta awon ile iwe fun aladani. Lara awon ehonu won tun ni pipin nnkan bi 3,000 awon elegbe won kuro ni aaye ti won wa lo si ibomiran ki asiko ti o ye ki won lo ni aaye ti won wa to, to, paapa julo awon ti won je asoju awon osise naa.
Ajo osise naa ti won so eyi tako oro ajoso awon ti o wa ye ni odun 2006, bakan naa tun ni aisa ile 15 fun awon ti ko si akamo ile eko unity ni ilu Abuja.

ENI NI AYAJO OJO AWON EWE.

O daju saka, awon ewe yoo tun bo sita lenii, lati lo se ayeye ajodun odun awon ewe bi won ti n se lodoodun, awon ewe yii naa sa ni ewa awon obi, ati ojo ola gbogbo orile ede kaakiri agbaye.
Awon ewe yii yoo bo siwaju awon gomina kaaakiri ipinle, ati alaga ijoba ibile kaakiri gbogbo orile ede Naijiria naa lenii, o daju inu awon gomina ati awon alaga ibile naa yoo si dun pe awon ogoweere yan niwaju won.
Leyin eyi, won yoo sa awon die ti won je omo eeyan pataki lawujo, koda ti awon ko tile yan ninu oorun bi awon omo talaka egbe won soto, won yoo se apeje fun won, o ba tan, odun pari, o tun di odun to m bo.
Awon gomina ati awon alaga kansu yii yoo sa awon omo olomo soorun, awon yoo wa labe iboji, won yoo ma ka iwe apile ko to je kiki ileri iro fun awon omo yii pe awon yoo se, sugbon ti a ba tu idi awon iroyin kayeefi yi wo, iro funfun ni a o ba nibe, agbara ki ni awon ogooweere yii yo sa lati ni ki won dake ki won ye paro fun awon.
Oju kii ti e ti awon ijoba wa lati je ki awon omo olomo ti o n wa fi ebi panu ma yan niwaju won, o di meloo ninu awon ijoba ti o ti koja oloogun tabi oloselu ti ko ti fi oju awon omo yii rare ri, eto eko ti mehe tan ni orile ede yii, awon to ba rije die, ile eko aladani ni won n ko awon omo won lo, e lo wo awon ile eko ijoba, ko si eyi ti o leero mo, nitori a i nigbagbo awon obi ninu eto eko ijoba mo ni.
Gbogbo eeyan ti awon omo wonyii ba fi inu ofifo yan niwaju yin, ti esi ntan won je, ti e n fi ojo iwaju won rare, ori won yoo bi yin o, o tan le nu o ku sikun, aabo oro la n so fun omoluabi ti o ba de inu re yoo di odindi.

Friday, May 22, 2009

GBENGA DANIEL FE TUN ONA OTA SE.

Gomina Ipinle Ogun, oloye Gbenga Daniel ti pase pe ki awon ajo ti o tun ona se(OGROMA) lo se ise gbogbo ona ti o wa ni agbegbe afara ti ijoba apapo se ti ni Sango ni ano.
Ise afara naa ti ise ijoba Olusegun Obasanjo bere ki o to fi ipo sile ni a gbo pe won ti pati bi odun meji seyin bayi, eyi ti o ti n nko laaasigbo ba awon oloko ati awon olugbe Sango.
Atejade ti o jade lati owo agbenuso gomina iyen ogbeni Adegbenro Adebanjo so pe ase yii wa lati ibi ipade apapo ti awon isejoba ipinle naa latari ati dekun iya ti o n je awon awako ati ara ilu.
Ninu atejade naa, o tun so siwaju pe ajo naa kanpa pe ki OGROMA se egbegbe afara naa mejeeji ati gbogbo agbegbe ona ti o yii ka lati le ri pe o rorun fun oko lati rin geere.

E SORA FOGUN ABELE ELEEKEJI

Ti ero iwe iroyin yii ba jo ti gbogbo onkawe yii patapata, e ni ti o ba sun mo awon ijoba, ki o so fun won ki won si n mi edo. Gbogbo ipinle kookan lorile ede yii ni Oluwa Oba adaniwaye fi n kan, kan tabi ekeji se ohun alumoni fun un, ki o ma je anfani fun won, bee naa si ni o se kaaakiri agbanla aye ibi ti o da awon eeyan, alujonu ati eranko toku sii.
Awon oyinbo amunisin to mu ile alawo dudu leru lemi ri bawi, ni se ni won da luuru po mo sapa, won o je ki a rin pade, ka ye ara wa wo boya a le ba ara wa se ki won to so oro di ojo to ro, to wa ko eyele po mo adiye. Ta ni ko mo pe eyele pelu adiye kii se egbe rara.
Oyinbo ti lo tan, won ti se ase mase, n je o wa ye ki awa ti won se bi won ti fe yii, naa ma tun le da inu ro bi. Awa ko fara mo iwa ti awon omo Ijaw n wu, be e si a ko fe ki awon ologun pa enikeni mo, ita eje sile ko ye wa lorile ede yii, ogun ko se enikeni lanfani, e je ki a fi pele kutu yanju oro ti o ba wa laaarin ara wa ni.

Sunday, May 17, 2009

AWON OLOPAA FAKO YO

Awon olopaa ni olu ilu NAijiria, ni Abuja, fa ako yo ni opin ose nigba ti won koju awon igaara olosa, ti won si pa merin ninu won, ti won si tun mu meji ti won ba ibon ak47, lowo won.
Nigba ti o m gbe oriyin fun awon akoni naa, Oga Olopaa Yan yan, Sir Mike Okiro ro awon isori olopaa to ku naa, lati tun bo mura si kikoju awon janduku naa ki a le, le ole kuro lawujo wa.

IJAMBA INA L'EKOO

Awon olugbe ipinle Eko ji lati gbo iroyin ijamba oko epo robi ti o jona ni ano, iyen 16/5/2009 ti o si pa awako ati omo eyin oko naa, ti won jona gbuugbu, ti ko si eni ti o le da won mo.
Isele naa ti o sele ni oju ona marose papa oko ofurufu Muritala Muhammed ni a gbo pe ogooro awon ero ni o ro lo si ibe.
Sugbon, ki awon olopaa ati awon osise panopano to de ibe, luputu ti hu, akuko ti ko leyin awon ti ijamba ina naa sele si.

FASHOLA SE BEBE FUN AWON ODO

Ni ojo bo, ti o koja, iyen 14/5/2009, Gomina Raji Fashola (Amofin Agba), ti Ile Eko, gbe igbese agba yanu nipa riranti awon ewe ninu isakoso re, o da awon odo pada si igba atijo ti won n se egbe odo wosowoso.
Igbese yii dara nitori ona kan pataki re lati dekun iwa odaran lowo awon omode, nitori irufe awon egbe yii ma ngbogun ti iwa ibaje lawujo ni.
Egbe odo wosowoso marun ni Gomina Fashola safihan re, awon ni egbe Boys Scout, egbe Sheriff Guards, egbe Boys Brigade, egbe Girls Guide ati egbe Red Cross.
A ro gbogbo gomina ipinle to ku lati gbe iru igbese gban kan gbi i naa ninu isakoso won, nitori ona kan re e lati kowo omo awon odo bo aso.