Sunday, June 28, 2009

IGBA OTUN DE, AYE FE YI PADA.

Igba otun ti de sile aye, e sa a wo, akoko, ni ile Amerika, won yan eeyan dudu lati di Aare ile Amerika, eyi ti won bura fun di Aare ninu osu kinni odun yii. Eyi tumo si gbigba adura ojo pipe ti awon olori alawo dudu ti n jeran iru nnkan bee, nigba ti won yan Barack Obama lati se Aare orile ede ti o lagbara julo ni agbaye.
Kayefi to tun wa sele nibe ni ti Ile Igbimo Asofin ile Amerika, ni ose to koja, ti won rawo ebe fun pe awon se owo eru ati rira tita awon eeyan ni orile ede naa ri.
Gege bi gbogbo wa ti mo, awa Afirika alawo dudu naa ni won n ra wo ebe si, nitori awa naa ni gbogbo re kangun le lori.
Boya ni eyin mo pe laaarin odun 1445 ati 1870 ti owo rira ati tita eru fi sele, o le ni milionu mewa alawo dudu omo ile Afirika ti o ba okoowo naa lo.
Leyin nnkan bi odun 233 leyin isele yii ni awon Amerika sese rojo ire ati be wa fun isele naa ti o da hila hilo sile, ti ko je ki awon omo Afirika roju raye se aye won bi won se fe ati ni iru eda ti Oluwa da won, awon oyinbo ni ko je ki a roju tu gbogbo nnkan ti a mo o se fun ra wa mo.
A ti n se ijoba wa bi ase fe, a n se okoowo asi n gbe bi ase le gbe pelu ara wa, ki won to rari wo wa laaarin. O le ni odun 400 ti won fi da wa ribo ribo, won wa n se wa bi eni pe kiise pe Oluwa jo dawa saye wa ko ipa kan tabi ekeji ni.
Sugbon, o ye ki inu wa dun ni asiko yii, pe o ti foju han gban gba, gban gba bayii pe won ti mo pe awon se si eledaa wa, won si ti toro aforiji, awon omo wa si ti n ba won jokoo se ijoba leleka o jeka ni orile ede agbaye kaaakiri, a n ba won kopa ninu iwe a si n bori ju won lo nigba miran, a n ba won se ere idaraya orisirisi, a si n je wo agbara ti Oluwa fi jinki wa pe okan naa ni wa, awo lasan ni o yato, awa kii se obo.

No comments:

Post a Comment