Monday, April 13, 2009

NI EKITI BAWO NI ATUNDI IBO YOO TI RI.

Ogbon kogbon lo m be ninu gbegi gbegi, ara kara lombe ninu gbenagbena, dana ogun dana ote kii se ina ire, iwa ika o to feni to ba ni Eledunmare, eyi i ga an loro to ba eto iselu to nlo lowo ni Ipinle Ekiti yii o. O da bi pe gbogbo ona ni egbe oselu PDP fe fi pada si ori aleefa yii, bakan naa ni egbe oselu AC to tako won ko sin mi edo.
O ye ki o ri bee, nitori ai duro nijo, ibeere ni ise. Sugbon o ye ki a jo yiri oro yii wo nitori gbogbo wa la jo n fe nnkan ti o dara, ohun ti o se pataki julo ti gbogbo omo eda ti Eledua da n wa naa ni igbe aye rere.
O se ni laanu pe lati bi odun kan abo seyin ti isejoba Aare Yar'adua ti bere, ko tii se abewo kaakiri ile Naijiria yanju, koda ko ti se e abewo si Ipinle Ekiti ri, o se wa je asiko atundi ibo ni Aare orile ede yii sese rojo rere lati de ipinle naa nitori pe o fe ki won di ibo won fun egbe oselu ohun pada sori aleefa.
Ka ni egbe oselu PDP ti pe aro ati odofin inu won po tele ni, ki won ti mu ni okukun dun fun enikeni ti o ba wole fun ipo ni abe asia won pe ki won se ijoba pelu eto ti won ba ni nile ti won ri pe yoo dun mo awon eeyan ninu, ko ba ti ma si pe won sese n se wahala ati inawo kiri, Oni ti fe e se bi odun kan abo, o ye ki ise ti o ba ti se sile o to fun awon eeyan lati yan pada si ipo.
Egbe oselu AC si je tuntun ni ipinle Ekiti, nitori teni to de lari a o mo ti alejo to m bo, ni Ipinle Eko ti won ti se ijoba, Fashola n gbiyanju, ti Fashola niyen, Oshiomhole ti o sese wole ni Edo, a o ti le so oun ti o fe gbese, Angeli Fayemi to m bo lona yii n ko, se yoo se rere, o ku si owo eyin oludobo Ipinle Ekiti ki e yan asoju rere fun ra yin.
Ohun ti iwe iroyin yii ka n fe ni pe, a fe ki aye rorun fun teru tomo lati gbe, ki ina oba o wa ni gbogbo asiko ti a ba fe lo, ki a ma a ri omi ti o dara mu, ki iwosan ti o peye wa fun t'eru, t'omo, ki oju ona to la geere wa ki awon eeyan ye sagbako ijamba oko loju popo latari ona ti ko dara, ki eto oro aje si kese jari, ka ri je rimu nirorun, ki abo ti o peye o siwa fun awa ati dukia wa.

No comments:

Post a Comment