Thursday, April 16, 2009

IRO M PA IRO FUN IRO

Asiri ti gomina ipinle P;ateau, iyen Jonah Jang pe awon ti sawari aaye kan ni bi ti won ko awon ohun ija oloro ti won tun fe fi sose ni ipinle naa si ye ko ko gbogbo eeyan lominu.
Ipnle naa ati ni pataki julo olu ilu naa Jos, ti padanu opolopo emi ati dukia ju ni bii odun meloo kan seyin, latari ija eleyameya tabi ija esin.
Koda, ninu iberu bojo ni awon ara ilu naa ati gbogbo awon eeyan to ba ni nnkan kan tabi ekeji se ninu ilu n wa ni gbogbo igba pelu iberu pe awon ko mo igba ti nnkan miran tun le sele.
Ko ye ki oro ri bee ti ko ba si pe ijoba o ki n fi taratara gbe igbese lori oro ti o ba ti jomo ti eleya meya tabi esin ko da ki won fi emi eeyan sofo ju bee lo.
Enu ya Gomina Jang pe pelu gbogbo igbese ti awon n gbe lati dekun aawo darudapo eleya meya ati elesin yii, awon kan tun n gbiyanju lati gbon owo re sinu awo ni. O ye ki o yaa lenu, sugbon ko gbodo jo loju nitori pe ninu gbogbo awon darudapo ti o n mu eleya meya ati esin dani, ti o si n mu emi awon eeyan lo, o di meloo ninu awon ajagun ta naa, ati awon to n ran won ni won wa lewon, tabi ti won ti gba idajo iku.
Pupo ninu awon darudapo yii ni won ma nse eto re daradara, ti awon to n na owo idi re si ma n je eeyan ti o nifon, leekan na lawujo wa, tabi meloo ninu awon to n na owo darudapo naa to wa lewon.
Gbogbo iwadi ti ijoba ti se lori awon oro ti o jomo darudapo esin ati eleya meya, o di melo o ti ijoba ti samulo re de oju ami. Wahala ati rogbodiyan to n tidi eleyameya ati ogun elesin sele o ni dawo duro, ayafi ti a ba to ni ijoba ti o mo bi won se n dari iru ilu to ba ni opolopo eya ati ogunlogo esin ninu.
O di igba ti a ba le ni ijoba ti o ba le je awon apaayan ni oruko esin tabi eya niya to gboopon ki won to le dekun iwa odaran yii.
O digba ti a ba le ni ijoba ti o ma gbagbo ninu orile ede Naijiria ju eya ati esin re lo nigba ti o ba kan ti ki a fi iya je odaran nipa esin ati eya.
Ni asiko odun ajinde ti o koja ni darudapo kan sele ni ipinle Niger, oro ti ko to ti e bakun gbe ni won ka sile pe o da wahala sile, awon olopaa ti ko opolopo eeyan, ti ti ojo meloo kan, won yoo ja awon die sile, leyin eyi ni ijoba yoo tun ko awon ajo kan jo lati se iwadi, leyin eyi won yoo ju iwadi won da si ibi kan, awon elese yoo ma ri n ma yan bii pe nnkan kan ko sele, bi eyi to sele nilu Jos, Kaduna ati awon ilu miran koja.

No comments:

Post a Comment