Wednesday, May 27, 2009

ENI NI AYAJO OJO AWON EWE.

O daju saka, awon ewe yoo tun bo sita lenii, lati lo se ayeye ajodun odun awon ewe bi won ti n se lodoodun, awon ewe yii naa sa ni ewa awon obi, ati ojo ola gbogbo orile ede kaakiri agbaye.
Awon ewe yii yoo bo siwaju awon gomina kaaakiri ipinle, ati alaga ijoba ibile kaakiri gbogbo orile ede Naijiria naa lenii, o daju inu awon gomina ati awon alaga ibile naa yoo si dun pe awon ogoweere yan niwaju won.
Leyin eyi, won yoo sa awon die ti won je omo eeyan pataki lawujo, koda ti awon ko tile yan ninu oorun bi awon omo talaka egbe won soto, won yoo se apeje fun won, o ba tan, odun pari, o tun di odun to m bo.
Awon gomina ati awon alaga kansu yii yoo sa awon omo olomo soorun, awon yoo wa labe iboji, won yoo ma ka iwe apile ko to je kiki ileri iro fun awon omo yii pe awon yoo se, sugbon ti a ba tu idi awon iroyin kayeefi yi wo, iro funfun ni a o ba nibe, agbara ki ni awon ogooweere yii yo sa lati ni ki won dake ki won ye paro fun awon.
Oju kii ti e ti awon ijoba wa lati je ki awon omo olomo ti o n wa fi ebi panu ma yan niwaju won, o di meloo ninu awon ijoba ti o ti koja oloogun tabi oloselu ti ko ti fi oju awon omo yii rare ri, eto eko ti mehe tan ni orile ede yii, awon to ba rije die, ile eko aladani ni won n ko awon omo won lo, e lo wo awon ile eko ijoba, ko si eyi ti o leero mo, nitori a i nigbagbo awon obi ninu eto eko ijoba mo ni.
Gbogbo eeyan ti awon omo wonyii ba fi inu ofifo yan niwaju yin, ti esi ntan won je, ti e n fi ojo iwaju won rare, ori won yoo bi yin o, o tan le nu o ku sikun, aabo oro la n so fun omoluabi ti o ba de inu re yoo di odindi.

No comments:

Post a Comment